matterMATTERS

Adape Ruga nile Yoruba: Ewu lori ayika iran Omo Alade

Ruga in disguise in Yorubaland: The consequential environmental danger

Lati owo: Sanya Adegbaye

Pansa omo alade o fura pansa won ti fe maa ja si na, aja wa o fura, aja ti n jin mowa lese, eyi lo mu ikanni alakoka ti matterMATTERS Yoruba fe ta iran omo alade ji lati mo ohun ti won ko mo tabi ohun ti o fi ara sin fun won lori ewu to n bo fun ayika won ati ero ngba awon ota fun iran yii.

Iroyin to mata lori ikanni matterMATTERS247 ti setan lati siju gbogbo iran omo alade si awon oun ti iran yii gba bi idagbasoke lori ayika won sugbon ti o je ewu ati erongba awon adari kan lati fi iran omo alade sinu ide ayika ojo iwaju ni.

A le fidi okodoro oro yii mule pelu alaye, awon orisirisi ona ti awon adari eya Fulani fe gba lati so iran Yoruba di akurete sugbon o seni laanu pe ete yi ko ye iran omo Alade rara.

Ikanni yi ko se tan la ti fun wa ni igbo didi san rara, e fara bale ka le ri pooro asiri oro eyi ti a fe la leseese fun wa.

Ti a ba wo ayika ti Adeda da iran omo Alade si daada, eyi ti n se gusu iwoorun orileede Nigeria, a o ri wipe gbogbo oun ti a fe bi igbo didi, odo, igi, eranko, ile olora ati opolopo ohun alumooni inu ile ni Aseda fi sodo si ayika wa gbogbo. Eyi gan an ni o di eru to n ba awon ota ile ati t’ode iran omo Alade ti won fi n ba ogun iran ojo iwaju re je ti ko si fura.

Akiyesi wa ni wipe ai ri ile wa gba fun Fulani nipa Ruga ti won beere fun n fi igba gbogbo n kowon lominu to fi je wipe awon iran afogun gbale onile yii, ti a mo si Fulani ko fi igba kan kan dekun lori bi won yoo se lee ja ayika iran omo Alade gba tabi ki won ba a je bi jijagba patapata ko ba rorun fun won boro, eyi lo fa irufe iwa ipa gbogbo ti e n ri lati owo won, bii ka daran wo oko oloko ka si je gbogbo irugbin ibe tan, bi oloko ba f’ohun konitohun o siba isele naa lo.

Orisirisi ona ni awon adari awon Fulani ati awon omo atoko wa baleje darandaran to n gbogun ti iran omo Alade fe gba lati ba ayika wa je fun igbeleke ati irolagbara iran ti won nikan soso. E je ka ti ibi isana kiye soogun, ti e o ba gbagbe, gbogbo wa la mo pe ise agbe ni ise ile wa lati aye baye wa ti o si je wipe ile, igbo ati odo ayika wa yi naa ni a n mu lo fun ise agbe naa. Sugbon ni asiko ti awa yi awon obayeje wonyii ti padi apo po pelu awon ojelu kan ninu iran awon omo Alade lati se suta si ayika wa gbogbo.

Lati bi odun mewa seyin, e o ri wipe isowo se ise agbe ni ona igbalode ni oke oya rugogo o si n gbooro lojoojumo sugbon ti awa ti Aseda fun ni ayika to dara n reyin nidi ise agbe yii to je ise amutorunwa wa.

Kini o fa eyi? E je ka yannana re ni sise n tele. Nje e sakiyesi owo tuntun to gbode kan bayi nile Yoruba? Owo taletale ni, o ti gbale gboko lori radio gbogbo! Awon akotileta kan ti ta gbogbo ile molebi ti won jogun ba tan, won ti sole ola dahoro. Awon ralerale na n pariwo wipe ile ohun naa waa fun kiko agboole olopo ile o n ero. Se eni ti ko tii rowo ounje lo fe rale ti yo si kole, nibi ti gbogbo aye ti n pariwo ebi? Awon wo lo n rale ohun lowo won? Aikiyesra ti n da Yoruba laamu ojo ti pe! Ka tile wa wipe Yoruba naa lo n rale ohun, to ba n se bayii lo, ko ni si ile kankan lati dako mo ni ojo iwaju ti ko pe mo, beeni ko ni si ile fun ile ise, lo ba tan, lo ba di ki a maa je ile taa ko repete sugbon ti a o rile dako mo, ti a o si ribi da ile ise si mo kawon omo wa o le rohun se.

Bi iran omo Alade ko ba le fura ti omi yii si papa teyin wogbin wa lenu, ko ni si ile fun ise agbe mo lojo iwaju, beeni gbogbo ibi ti o ye ko je ibudo ile ise nla nla ni yoo ti di ilegbee tan pata bi mo se so.

Photo credit: Amen Estate

Ti eyi ba ti di oun ti o wa si imuse, o di ki iran omo Alade maa ra ounje wo le ni keti keti lati oke oya wa sile, eyi a wa mu ki oro aje won lo soke daada ti oro aje awa t’Aseda jogun ise agbe ohun fun a wa maa ra mun un loju kan bi omi inu eku nitori aikiyesara on ojukokoro owo aitojo, a wa di wipe a ti daran sile domo. Tabi eyin o ro wipe ota ode ti le darapo mo tile, ki won gbowo fun won lati fi gbale t’Aseda jogun funwa lona ero?

Koni yami lenu ti a ba bere sini ri Fulani Estate nile Yoruba, se bi eni to lowo lo laja. Emi a maa beere ibeere kan lowo awon akotileta to n ta gbogbo awon ile molebi fun awon to de losan kan oru kan yii wipe se kani baba n la baba won ti ta ile ohun tan, kini awon maa deba? Eyin e lo wadi oro wo irufe awon to n rale ti won n pariwo lori radio gbogbo, melo ni Yoruba to wa laarin won? beeni ati mo lataye baye wipe bawon ara oke ohun ba fe ba wa ja nile yii, ara wa naa ai won moo ran siwa. Idi niyi to fi je wipe opo to n rale molebi kaakiri loni, iran omo Alade naa ni gbogbo won, beeni mi o si lodi si konikaluku sowo to ba mo, sugbon se ko lowo kan eru ninu, se kii se ajomo awon to fe gbale gboko wa lowo wa? Boya kawon taletale si bawa dahun ibeere yii wipe irufe awon wo lo n rale ohun lowo won lopo yanturu? Beeyan ba si ti rale to sanwo, se e fe wi fun wipe ko leto lati so ibe loruko to wuu, nitorina n ko, o le pe ibe ni Ruga tabi Gaafu (Gaa Fulani), se bi o ti fun wa lowo taafe, awa naa si ti funwon logun wa. Bi e o ba gbagbe, olori awon darandaran ti figba kanri so ni gbangba wipe awon ti doyi ka wa nibi gbogbo; bi eyi o ba ri be, okuku jo be, nitori ojoojumo niwon n wolu ni ketiketi, leyi to seese ko je ibi ti won n raa sile ni won a pago si. E lo re ko oro mi sile, keesi sami si!

Bi e o ba mo, eyi ni kan ko ni won n gba lero, won n wa ki gbogbo igbo ati igi nla nla ti Aseda fi rowa lagbara ni ile wa di asale bi ti oke oya.

Ni akotan, matterMATTERS Yoruba fe pe gbogbo iran Omo Alade sakiyesi, paapa julo awon Oba at’ijoye, ki won o se kilokilo fun gbogbo awon taletale ki won o ye fawa le oni dilaali lowo mo, kiwon o ye ko tile pekun ode, ki won o ye tale baba nla wa fawon ajeji mo, eje ka moo ranti Afonja nilu Ilorin! Bi o ba wa pon dandan ka tale, e je ka yaa soto lejowonlejowon, k’ile oko funse agbe o wa laaye oto gedengbe, ka ma se reni ti yoo ta irufe ile bee funle kiko; k’ile ikole naa o wa loto ko da duro; beeni ka ni t’ileese naa laaye oto kaakiri taamo si industrial estates nitori itose bayii lo l’Oyo, Onibode lo l’aafin.

Share the Post:

Related Posts

This Headline Grabs Visitors’ Attention

A short description introducing your business and the services to visitors.